Ìtúpalẹ̀ Àṣàyàn Àkóónú Oríkì Ilẹ̀ Yorùbá
Keywords:
Oríkì, Oríkì-orílẹ̀, Àwùjọ Yorùbá, Ìtúpalẹ̀, ÀṣàyànAbstract
Oríkì jẹ́ ẹ̀yà lítíréṣọ̀ kan tí ó jinlẹ̀ púpọ nínú gbogbo lítíréṣọ̀ alohùn Yorùbá nítorí pé ó jẹ́ orísun ìtàn, ẹ̀sìn, ìṣe, ìṣesí, ìfẹ́, èèwọ̀, iṣẹ́ ìran, àbùdá ìrísí àti ìwà ìran kan. Yàtọ̀ sí èyí, oríkì kò mọ ní ti ẹ̀dá ènìyàn nìkan, Olódùmarè, àwọn òrìṣà àkúnlẹ̀bọ, àwọn ẹranko àti ẹyẹ náà ní oríkì tiwọn. Àwọn nǹkan mìíràn bí kòkòrò, òkè, ilẹ̀, odò, igi, ewé, àwọn oúnjẹ ìbílẹ̀, èso, àìsàn, àrùn àti àwọn nǹkan mìíràn náà ní oríkì tiwọn lọ́kan-ò-jọ̀kan. Èyí fi hàn wá pé oríkì gbòòrò púpọ̀ àti pé kò fẹ́rẹ̀ sí ohun tí ó wà lórílẹ̀ ayé yìí tí Olódùmarè dá tí kò ní oríkì tirẹ̀. Oríkì, pàápàá oríkì orìlẹ̀ máa ń farahàn nínú gbogbo ìṣèré àwọn akéwì tàbí apohùn Yorùbá. Ìṣàmúlò oríkì nínú ìṣèré wọn máa ń fi wọ́n hàn gẹ́gẹ́ bí akéwì tó dáńtọ́ láwùjọ Yorùbá. Nínú iṣẹ́ ìwádìí yìí, a wo ìtumọ̀ àti àbùdá oríkì Yorùbá. A tún ṣe ìtúpalẹ̀ àkóónú àṣàyàn oríkì tí ó tọ́ka sí àṣá, ẹ̀sìn, ìṣe, èèwọ̀, ìtàn, ẹbí ohun tí ó jẹ́ àléébù àwọn ìran wọ̀nyí. Àbájáde iṣẹ́ ìwádìí yìí fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé oríkì máa ń roni, àlàjẹ́ a sì máa ro ènìyàn. Oríkì a máa mù orí ẹni wú, ó máa fúnni ní ìgboyà pẹ̀lú ìmọ̀lára, ó máa ń júwe orírun ẹni, ó sì máa ń fini lọ́kànbalẹ̀ pé ojúlówó ọmọ ìran báyìí ni irú ẹni bẹ́ẹ̀ jẹ́. Ọ̀kan lára àwọn ogún ìní ìran kọ̀ọ́kan ní ilẹ̀ Yorùbá ni oríkì jẹ́, a kò gbọdọ̀ jẹ́ kí ó parun.