Ìlò Àwàdà fún Yíyanjú Ìṣòro Ìbára-ẹni-gbé-pọ̀ Ajẹmọ́dìílé Gẹ́gẹ́ BIí Ó Ṣe Hàn Nínú Àwọn Àṣàyàn Ìwé Eré-Onítàn Yorùbá

Authors

  • Grace Oluwakemi Adefowope Our Lady of Apostles Secondary School, Ijebu-Ode Author

Keywords:

Àwàdà,, Ìbára-ẹni-gbé-pọ̀, Ìkóra-ẹni-níjàánu, Ìṣòro, Ìdílé

Abstract

Àṣamọ̀
Ohun tí ó bí iṣẹ́ ìwádìí yìí ni àwọn ìṣòro tí ó ń kojú ìbára-ẹni-gbé-pọ̀ nínú ètò ìdílé àti ipa tí àwọn ìṣòro wọ̀nyí ní lórí àwùjọ. Lára àwọn ìṣòro wọ̀nyí ni ìfojútẹ́ńbẹ́lú-ẹni, ìfẹ̀mí-òkùnkùn báni jà, àìnímọ̀ọ́tótó, ìjà, ìmẹ́lẹ́, àìnítẹríba,àìlẹ́kọ̀ọ́-iléàti àṣìlò ọmọ-ọ̀dọ̀.Èròńgbà iṣẹ́ ìwádìí yìí ni láti wò bí ìlò àwàdà ṣe lè yanjú ìṣòro ìbára-ẹni-gbé-pọ̀ ajẹmọ́dìílé nípa ìfòótọ́-ọ̀rọ̀ gún aṣebi lára nípasẹ̀ ẹ̀rín rírín, kí ó lè jẹ́ àríkọ́gbọ́n fún ẹlòmíràn. Ọgbọ́n iwádìí tí iṣẹ́ yìí tọ̀ ni ṣíṣe ìtúpalẹ̀ kíkún lórí àkóónú àṣàyàn ìwéeré-onítàn méjì, ìyẹnÌyá Yáádì tí Dòsùmú kọ àti Nítorí Owó tí Ìṣọ̀lá kọ láti wo bí àwọn òǹkọ̀wé ṣe lo àwàdàfúnyíyanjú àwọn ìṣòro ìbára-ẹni-gbé-pọ̀ ajẹmọ́dìílé.Tíọ́rì ìfojú-ìmọ̀-ìbára-ẹni-gbé-pọ̀-wò-lítíréṣọ̀ ni ọ̀pákùtẹ̀lẹ̀ tí iṣẹ́ yìí rọ̀ mọ́ nítorí pé láti inú àwùjọ ni ìlò àwàdà ti máa ń jẹ yọ.Iṣẹ́ ìwádìí yìí ríi pé lára okùnfà ìṣòroìbára ẹni-gbé-pọ̀ ajẹmọ́dìílé ni àìnífẹ̀ẹ́, àìnísùúrù, àìkọ́mọ-lẹ́kọ̀ọ́-ilé tó àtiàìníṣẹ́. Iṣẹ́ ìwádìíyìí gbà pé ìlò àwàdà kó ipa ribiribi nínú yíyanjú ìṣòro ajẹmọ́dìílé dé àyè kan gẹ́gẹ́ bí ó ṣe hàn nínú àwọn ìwé àmúlò. Ọ̀nà àbáyọ tíIṣẹ́ ìwádìíyìí dábàá ni pé àwùjọ fi àyè gba ìlò àwàdà gẹ́gẹ́ bíi ijánu fúnìwà ìbàjẹ́, kí ẹ̀mí ìkóra-ẹni-níjàánu lè fẹsẹ̀ múlẹ̀ síi nínú ìdílé, kí àwọn tí pẹ̀tẹ̀pẹ́tẹ̀ àwàdà bá ta sí lára gbìyànjúláti ṣe àtúnṣe.

Downloads

Published

2025-09-22