Àgbéyẹ̀wò Ìṣọwọ́lò-Èdè Inú Orin Àjàgbó Ní Ọ̀gbàgì-Àkókó
- Authors
-
-
Mistura Ayobami Tábí-Àgòrò, Ph.D.
Author
-
Bákàrè, Wahab Táíwò
Author
-
- Keywords:
- Ìṣọwọ́lò-èdè, Odún ìbílẹ̀, Orin Àjàgbó, Ọ̀gbàgì-Àkókó, Tíọ́rì ìfojú-ìmọ̀-ìbára-ẹni-gbépọ̀-wo lítíréṣọ̀. (Stylistic features, Festival, Àjàgbó’s songs, Ògbàgì Àkókó, Sociology of literature)
- Abstract
-
Àṣamọ̀
Orin inú ọdún ìbílẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn adùn tó ń mú kí ọdún ìbílẹ̀ ṣeé wò. Orin Àjàgbó ti ìlú Ọ̀gbàgì-Àkókó ni a fi orí iṣẹ́ ìwádìí wa yìí sọ. Ọ̀pọ̀ ọdún bí ọdún Egúngún, Imọlẹ̀, Ògún àti Ọjà-Olorì ni wọ́n wà ní ìlú Ọ̀gbàgì-Àkókó, tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì ní ìpohùn nínú, ṣùgbọ́n ìpohùn inú ọdún Àjàgbó ní ìlú Ọ̀gbàgì-Àkókó ló jẹ wá lógún. Èròǹgbà iṣẹ́ ìwádìí yìí ni pé, orin Àjàgbó jẹ́ ọ̀kan gbòógì lára àwọn orin tó wà nínú ọdún ìbílẹ̀ ní ìlú Ọ̀gbàgì-Àkókó. Èyí gan-an ló mú wa yan orin náà láàrin àwọn orin yòókù. Bákan náà, ọ̀pọ̀ iṣẹ́ lámèétọ́ ni àwọn onímọ̀ ìṣáájú ti ṣe lórí iṣọwọlò-èdè, láti wo bí apohùn tàbí olùṣẹ̀dá iṣẹ́-ọnà aláwòmọ́ lítíréṣọ̀ kan ṣe lo èdè nínú èyíkéyìí lítíréṣọ̀ tí ó bá gbé kalẹ̀, ṣùgbọ́n kò tíì sí iṣé kankan tó jẹ mọ́ wíwo ìṣọwọ́lò-èdè nínú ìpohùn inú ọdún Àjàgbó ní ìlú Ọ̀gbàgì-Àkókó. Láti dí ààyè yìí la ṣe yan kókó-ọ̀rọ̀ náà. Tíọ́rì ìfojú-ìmọ̀-ìbára-ẹni-gbépọ̀-wo lítíréṣọ̀ ni a lò fún iṣẹ́ ìwádìí yìí, láti ṣàtúpalẹ̀ ìṣọwọ́lò-èdè inú orin Àjàgbó náà. A ṣe àkójọ àwọn orin Àjàgbó tí a lò nínú iṣẹ́ yìí ní oko ìwádìí tí a lọ.
Abstract
Festival song is one of the reasons that make Yorùbá festivals aesthetic. This paper focuses on Àjàgbó’s songs sing during Àjàgbó festival in Ògbàgì Àkókó. There are festivals like Egúngún, Imọlẹ̀, Ògún, Àjàgbó and Ọjà-Olorì that encompass different songs in Ògbàgì Àkókó, but we focus on the orature in Àjàgbó Festival alone in this work. This happens because orature in Àjàgbó Festival is the best among others found in Ògbàgì Àkókó’s Festivals. Also, works have been done on the stylistic features of orators’ works, but no one has carried out research on the stylistic features of Àjàgbó Songs used during Àjàgbó’s Festival in Ògbàgì Àkókó. This is the gap we want to fill. We use sociology of literature for this analysis and data were collected at the reseach field.
- References
- Cover Image
-
- Downloads
- Published
- 2026-04-30
- Section
- Articles