OJÚṢE ÌTÀKÙN ÌBÁNIDỌ́RẸ̀Ẹ́ ÀTI AṢÀTAGBÀ TIKTOK ÀTI YOUTUBE LÓRÍ ÌDÀGBÀSÓKÈ Ẹ̀KỌ́-ÈDÈ ÀTI ÀṢÀ YORÙBÁ
- Authors
-
-
Mistura Ayobami Tabi-Agoro, Ph,D.
Author
-
ISHOLA Sauban Alade, Ph.D.
Author
-
OYAGBENJO Abiodun Oyesoji, Ph.D.
Author
-
- Abstract
-
Ọ̀kan lára àǹfààní tí ìmọ̀-ẹ̀rọ ìgbàlódé mú bá ìbánisọ̀rọ̀ ní àwùjọ ni àwọn ìtàkùn ìbánidọ́rẹ̀ẹ́ àti ìtànkálẹ̀ ìròyìn. Ìtàkùn ìbánidọ́rẹ̀ẹ́ àti ìtàkùn aṣàtagbà TikTok àti YouTube ń kó ipa ribiribi lórí ìdàgbàsókè ẹ̀kọ́ èdè Yorùbá ní orílẹ̀-èdè yìí àti òkè-òkun. Ìdí nìyí tí iṣẹ́ ìwádìí yìí fi ṣe àgbékalẹ̀ ọ̀nà tí wọ́n ń gbà mú ìdàgbàsókè bá ẹ̀kọ́ èdè Yorùbá nípasẹ̀ ìtànkálẹ̀, ìpolongo àti ìdàgbàsókè ẹ̀kọ́ èdè Yorùbá. Iṣẹ́ ìwádìí yìí ṣe àmúlò ẹ̀rọ ayélujára láti wá ẹ̀rí-máa-jẹ́mi-nìsó láti ṣe àgbágbè èrò wa nínú iṣẹ́ yìí. Èyí yóò tún fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé, àwárí ìmọ̀ nípa àṣà jẹ́ iṣẹ́ gbòógì tí ẹ̀rọ ayélujára àti ìtàkùn ìbánidọ́rẹ̀ẹ́ ń ṣe. Fún ìdí èyí, owó àwé náà la ó fi ṣe àwé lálejò nítorí pé orí ẹ̀rọ ayélujára náà la ó ti ṣe àkójọ èdè fún àyẹ̀wò. Àwọn ìwé àkànṣe, ìwé ìwádìí àti jọ́nà lóríṣìíríṣìí náà yóò wúlò fún wa láti ṣe àmúlò díẹ̀ nínú ọgbọ́n àwọn asáájú lórí kókó-ọ̀rọ̀ yìí nítorí pé, a-fọgbọ́n-ọlọ́gbọ́n-ṣọgbọ́n kì í tẹ́ bọ̀rọ̀. Àbájáde ìwádìí fi hàn pé, Youtube àti Tiktok ń kópa pàtàkì nínú ìdàgbàsókè àti ìgbélárugẹ àṣà Yorùbá pàápàá jùlọ ní abala ìtànkálẹ̀ àṣà yìí ní orílẹ̀-èdè yìí àti ní òkè òkun níbi tí a kò lérò pé ó lè dé. Ìtàkùn ìbánidọ́rẹ̀ẹ́ nípa pàtàkì lórí ìtànkálẹ̀, àtúnṣe àsìsọ àti àsìkọ èdè Yorùbá, ẹ̀kọ́ àṣà àti èdè Yorùbá, pàápàá jùlọ abala òwe tó máa ń jẹ́ ìṣòro fún àwọn èwe òde-òní. Iṣẹ́ ìwádìí yìí dá a lábàá pé kí àwọn òǹkọ̀tàn, àwọn òǹpèdè, àwon olùwádìí lórí èdè Yorùbá túnbọ̀ tẹpẹlẹ mọ́ ṣe ìwádìí ìjìnlẹ̀ lórí èdè Yorùbá, kí wọ́n sì má tẹ̀tì nínú fífi ṣọwọ́ sórí afẹ́fé ̣nítorí pé ohun tí a bá fi pamọ́ kò níyì mọ́ láyé àlàbọrùndẹ̀wù ti ayé ti ń lu jára wọn yìí. Alójúlódì ni àfihàn àṣà àti èdè Yorùbá lórí ayélujára, bí ó ti ń ṣe àfihàn ire náà ló ń ṣe àfihàn aburú tí kò yẹ kí àwọn ènìyàn máa rí gẹ́gẹ́ bí ìwúrí.
- Author Biography
- References
- Cover Image
-
- Downloads
- Published
- 2026-04-30
- Section
- Articles