Ìmọ̀ Ìjìnlẹ̀-Èrò Yorùbá àti Ìbáyému Nínú Àṣàyàn Orin Yẹ̀kínì
- Authors
-
-
Comfort Olatunji Efemini
Adeyemi Federal University of Education, Ondo.
Author
-
- Abstract
-
Ohun tí ó máa ń jẹ oníṣẹ́-ọnà aláwòmọ́ lítíréṣọ̀, ìbá à jẹ́ ewì alohùn, tàbí ewì àpilẹ̀kọ lógún ni láti ri pé ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ èrò wọn bá ìṣẹ̀lẹ̀ àwùjọ mu ní gbogbo ọ̀nà. Káríayé ni orin jẹ́, káàkiri ilẹ̀ adúláwọ̀ àti ilẹ̀ aláwọ̀ funfun ni orin ti jẹ́ kòṣeémánìí nínú ìgbésí ayé àwọn ènìyàn àwùjọ. Ajíbádé àti Rájí (2011) fi èrò wọn hàn nípa ewì alohùn Yorùbá pé ó wà láti dáàbòbo ìgbékalẹ̀ àwùjọ, ohun tó jẹ mọ́ ìwà àpọ́nlé tàbi ìwà àbùkù láàrin àwùjọ a máa jẹyọ nínú ewì wọn lóòrè-kóòrè. Ọlátúnjí (1982) gbà pé ewì jẹ́ ọ̀nà kan pàtàkì tí àwọn ènìyàn ń gbà fi èrò ọkàn wọn hàn fún àwùjọ. Wakepedia (2016) tí ó jẹ́ àkọsílẹ̀ yaágbó-yaájù, lórí ẹ̀rọ fóònù alágbéká sọ nípa ewì báyìí pé:
Poetry is a form of literary art in which language is used for its aesthetic and evocative qualities in addition to or in lieu of its apparent meaning.
(Ewì jẹ́ iṣẹ́ ọnà aláwòmọ́ lítíréṣọ̀ èyí tí ó jẹ́ pé èdè ni a fi ṣe àbùdá ẹwà àti adùn rẹ̀ ní àfikún sí tàbí ní ìrọ́pò sí ìtumọ̀ tí ó yẹ kí ó ní).
Ohun tí Wakepedia (2016) ń sọ ni pé iṣẹ́ ọnà aláwòmọ́ lítíréṣọ̀ ni ewì jẹ́, èdè tí ó kẹnú, tó jinlẹ̀ tó sì jíire ni a sì fi máa ń gbe jáde. Ìtumọ̀ àti èrò rẹ̀ a sì máa jinlẹ̀ ju ọ̀rọ̀ ṣákálá lọ. Èrò ìjìnlẹ̀ Yorùbá sì máa ń farahàn nínú irú àwọn ewì bẹ́ẹ̀. Ewì Yorùbá èyí tí orin jẹ́ ọ̀kan nínú wọn máa ń ní nǹkan pàtó tó dá lé lórí. Ìjìnlẹ̀ èrò tí a fi àrògún gbé kalẹ̀ lọ́nà tó dùn tó sì ní iṣẹ́ tí ó ń jẹ́ ni ewì. Àfojúsùn iṣẹ́ ìwádìí yìí ni láti ṣàfihàn ìmọ̀ ìjìnlẹ̀-èrò tí ó sodo sínú orin Yẹ̀kínì Àjàó. Àbájáde rẹ̀ sì fi hàn pé àgbékalẹ̀ orin Yẹ̀kínì Àjàó kún fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìmọ̀ ìjìnlẹ̀-èrò Yorùbá èyí tí ó fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé èso àwùjọ ni orin rẹ̀. Tíọ́rì ìfojú-ìmọ̀-ìbára-ẹni-gbé-pọ̀ wo lítíréṣọ̀ ni a fi ṣe àtúpalẹ̀ iṣẹ́ yìí.
- References
- Cover Image
-
- Downloads
- Published
- 2026-04-30
- Section
- Articles